Hymn 1000
Fa mi lo si Apata ti o ga ju mi lo
Scripture: OD. 61:2
1
fMo ntesiwaju l'ona na
Mo ngoke si lojojumo
mpMo gbadura bi mo ti nlo
Oluwa jo gbe mi soke,
CHORUS
fOluWa, jo gbe mi soke
Fa mi lo si ibi giga
Apata t’o ga ju mi lo
Oluwa jo gbe mi soke.
2
fIfe okan mi ko kuro
Larin 'yemeji at'eru
Awon miran le ma gbe be
Ibi giga l'okan mi nfe
3
fMo fe ki nga ju aye lo
B'esu tile ngbogun ti mi
Mo nfi gbagbo gbo orin na
Ti awon mimo nko loke.
4
fMo fe de 'bi giga julo
Ninu ogo didan julo
Mo ngbadura ki nle de be
Oluwa mu mi de 'le na.
5
fFa mi lo si ibi giga
Laisi Re nko ni le de ’be
Fa mi titi d' oke orun
Ki nkorin lati ’ibi giga.