Hymn 104
Eni ti o fe wa, ti o si we wa ninu eje Re kuro ninu ese wa: Tire li ogo ati ijoba lae ati lae:
Meter: C.M. & Ref.
Scripture: Amin. Ifi. 1:5-6.
1
mfGbo orin awon ayanfe
Orin iyin titun;
T ’od’agutan t’a se logo
Eyi ni orin won:
CHORUS
f“Ogo f’Eni to fe wa,
To f’eje Re we wa,
To w’ese at’ebi wa nu
Nibi ’san iye ni.”
2
mfA fo aso wa n’n’eje Re
O si funfun laulau;
Imole t’O tan s’okan wa
F’ipa oto Re han.
3
fA segun nipa eje Re
’Gbat’ esu gbogun de,
Agbara otito Kristi
Lo f’okun s’apa wa.
4
Ka juba Od’agutan na
Baba ’ye on mole
Tire l’ogo, ola, ipa,
’Joba at’agbara.