Hymn 105
Ohun opolopo eniyan nwipe, Alleluya.
Meter: 8.7.8.7.D.
Scripture: Ifi. 19:6.
mfGbo orin ‘yin dida aye,
T’egberun orile nko,
Orin didun bi t’angeli,
O ndun bi omi pupo,
“Bukun, ogo, ipa, ‘gbala
Fun Olorun lor’ite,
Baba, Omo, Emi mimo
Olola ‘lainipekun
mfLati ebute otutu
Lor’ olubuluku ‘le
Lat’ opolopo eniyan
Ilu alawo pupa,
‘Lawo dudu t’a da n’ide,
Funfun ti o po niye,
Ominira alarinkiri
De ‘le awon Arabu
mfLati ebute otutu
De ile ti o mooru,
Awon olokan gbogbona
Awon olokan gbigbona
Leba okun Pasifik;
Lati ‘opo aimoye okan
Onigbagbo alayo,
Awon to nsona bibo Re,
Won fere de sion’ na
crAkojo orile-ede,
Lat’inu eya ahon,
Gbo, won nkorin iyin titi,
Gbo orin ologo ni,
O b’afonifoji mole,
O si ndun lori loke,
f0 ndun siwaju tit’o fi
Kun ibugbe Olorun.
pGbo, didun orin na dapo
Mo orin awon t’orun,
Awon t’o koja n’nu ’danwo
Sinu isimi loke,
crWon wo aso ailabawon,
mfImo ’segun lowo won,
Won nfi duru ko Hosana,
Ni ’waju Olorun won.
f“Ogo fun Eni t’o fe wa,
T’O we wa n’nu eje Re.
K’oba, alufa, ma korin
Si Baba, Olorun wa.
K’eeyan mimo on Angeli,
Ko Aleluya titi:
Asegun orun apadi:
Olodumare joba.”