Hymn 109
Ogo ni fun Olorun loke orun.
Meter: 7.7.7.7.
Scripture: Lk. 2:14.
1
fE fi ogo fun Baba,
Nipa Eni ti a wa;
O ngbo adura ewe,
O nf’eti si orin won.
2
fE fi ogo fun Omo,
Kristi, ’Wo ni Oba wa;
ffE wa, e korin s’oke,
S’Od’agutan elese
3
fOgo fun Emi Mimo,
Bi ojo Pentikosti;
Ru aya awon ewe,
F’orin mimo s’ete won.
4
ffOgo ni l’oke orun,
Fun Eni Metalokan;
Nitori ihin rere,
Ati ife, Olorun.