Hymn 117
Kiyesi i, O mbo ninu awosanma.
Meter: 10.8.10.7.10.11.10.7.
Scripture: Ifi. 1:7.
ffJesu mbo l’ofurufu pel’ayo,
fOjo ayo! ojo ayo!
mfAwon t’o fe yo fo lo pade Re,
fOjo ayo! ayo nla.
Won yo pade Oluwa ni sanma,
Gbogbo wa pelu Jesu yo wa nibe,
Ao bo lowo aniyan at’aro;
Ojo ayo! ayo nla!
mfAwon obi, omo yo tun pade;
fOjo ayo! ojo ayo!
Arakunrin pelu arabirin,
Ojo ayo! Ojo nla
Won mbe l’odo Krist’ a ko ri won mo,
crIbanuje ni lilo won je fun wa;
Sugbon ao pade laipe pel’ayo,
mfOjo ayo! ayo nla!
Gbogbo wa ha setan fun bibo Re?
Ojo ayo! ojo ayo!
Qmode ati agba ha se tan!
Fojo nla! Ojp ayo!
A nfe lati wa l’odo Re laelae
K’a le ma wo oju ati ewa Re,
Eyin ara, e korin nitori
Qjo nla na t’ao pade.
fAwon miran ko ni le ba wa ko
Orin ayo ti ojo na!
Sugbon gbogbo wa ni ayo mbe fun
ffOjo ayo! ojo nla;
mf’Tori Jesu nduro sibesibe,
K’a le mura tan nipa agbara Re,
Ninu ogo didan Re k’a le ni
Ibugbel’oke orun.