Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 118

Nitorina e ma sona; nitori eyin ko mo wakati ti Oluwa nyin yio de.

Meter: 15.15.15.15. & Ref.

Scripture: Mat. 24:42.

1

mfAwa nsona, awa nduro titi ’boji y’o fi ya,

T’Oluwa pelu awon ayanfe y’o de n’nu ogo,

Nigbati a o gbo ipe Olorun jakejado,

Oku n’nu Kristi y’o si ji lati wa l’odo Re lae.

CHORUS

crAwa nsona, awa nduro,

Fun imole ti ojo nla na,

Fun bibo Olugbala wa

Pelu awon ayanfe

2

mfAwa nwo ona fun bibo Oba wa nla Ologo,

Eni ti yo le ibi ati okunkun lo jina,

’Gbat’ ododo ati anu Re yio bori l’aye

Ti asia Re yo si ma fe lori gbogbo aye.

3

Awa nfi ’gbagbo wo ’joba Re ti egberun odun,

Ati opo awn emewa Re ti a ra pada,

Okan wa si nkepe. “Ma bo k’a ba le ri ogo Re'

Ki a le ma ba gbe ninu ogo ti ayeraye.