Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 122

Ohun eniti o mi aye nigbana.

Meter: 8.7.8.7.8.8.7,

Scripture: Heb. 12:26.

1

ffOluwa, agbara fo ’hun

Bi ara l’oke Sinai,

Awon Israeli gb’ohun Re,

Won si gbon fun iberu;

Okunkun su biribiri,

Ati l’otun atil’osi

ffAwon apata n faya

2

pOluwa ife je irora

Lori oke Kalfari,

O gbe oju soke orun,

L’akoko wahala Re;

Fun wa lo ru eru egbe

Fun wa l’o teje Re sile,

T’o si tu Baba l’oju.

3

mfOba ife at’agbara

Oluwa eda gbogbo

crO npada bo ninu ogo

Lati wa gba ijoba;

ffIpe y’odun, angel’ y’o ho,

Aleluya y’o j’orin won,

L’ori esu at’iku.