Hymn 127
Olurapada yio si wa si Sioni.
Meter: 8.8.8.8.8.8.
Scripture: Isa. 59-20
1
mfSum’odo wa Imanuel’,
Wa ra Israeli pada,
pT’o nsofo li oko eru,
Titi Jesu y’o tun pada.
CHORUS
ffEyo, e yo! Imanuel’,
Y’o wa s’odo wa, Israel
2
mfWa, opa Alade Jese,
K’o gba wa l’owo ota wa,
Gba wa l’ow’ orun apadi.
Fun wa ni ’segun l’ori ’ku.
3
Sunmo wa,’WO ila orun,
Ki bibo Re se ’tunu wa,
Tu gbogbo isudede ka
M’ese ati egbe kuro.
4
mfWa, Omo, ’lekun Dafidi,
’Lekun orun y’o si fun O
Tun ona orun se fun wa;
JO se ona osi fun wa.
5
Wa Oluwa alagbara,
T’o f’ofin fun eniyan Re,
Nigbani, l’or’ oke Sinai,
Ninu olanla pel’ eru.