Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 128

Emi o si tun pada wa.

Meter: L.M.

Scripture: Jn. 14:3

1

mfL ’eba odo Jordani ni

Oni ’ribomi nke wipe

fOluwa mbo! Oluwa mbo,

E gbo ’hin ayo! Qba mbo!

2

K’ese tan ni gbogbo okan,

K’Olorun ba le ba wa gbe;

K’a pa ile okan wa mo

Ki alejo nla yi to de.

3

Jesu, IWO n’igbala wa,

Esan, ati alabo wa,

B’itanna l’awa ba segbe

Bikose t’ore-ofe Re.

4

S’awotan awon aisan,

Gb’elese to subu dide,

Tan ’mole Re ka bi gbogbo,

Mu ewa aye bo s’ipo.

5

K’a fiyin f’omo Olorun;

Bibo eni mu dande wa

Eni t’a nsin pelu Baba

At’Olorun Emi Mimo.