Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 13

Olorun si wipe, Ki imole ki o wa; imole si wa.

Meter: 8.7.11.8.7.11 & Ref

Scripture: Gen. 1:3

1

mf‘Mole wa l’afonifoji

‘Mole wa l’ori oke

Jesu l’O mu wa s’aye Okukun yi,

‘Mole wa l’ara itanna

To ndagba l’eba odo,

Imole wa ni ‘bikibi ti mo nlo;

CHORUS

F‘Mole, Mole t’ife Re orun,

‘Mole, mole, itansan orun

‘Mole, mole, li aye wa yi,

‘Mole, mole, l’ona ani Gbogbo

2

mfImole wa lori pada

Ati l’ori koriko

Nibiti awon eye nkorin iyin;

Imole wa lori oke,

‘Mole wa ni petele

Je ki gbogbo eda jumo korin ‘yin

3

fB’aye tile kun fun ‘mole

To si ntan l’ojojumo,

Okan pupo wa n’nu okunkun Sibe,

Ti ko gb’oruko Jesu ri,

Tabi ife ‘yanu Re,

Je ki a fi oro Re ran won L’owo