Hymn 131
Kiyesi i, O mbo li awosama.
Meter: 8.7.8.7.4.7.
Scripture: Ifi. 1:7
1
mfOluwa l’awosanma,
O mbo l’ogo l’ola Re,
Enit’a pa fun elese.
Mbo pelu Angeli Re;
ffAleluya!
O was’aye wajoba.
2
Gbogbo eda, wa wo Jesu,
Aso ogo l’a WO fun;
pAwon t’o gan, awon t’o pa
T’o kan mo agbelebu.
ppWon o sokun,
Bi won ba ri Messiah.
3
Awon apa iya t’O je
Han li ara didan Re,
Awon eni irapada,
Wole, fun t’ayo t’ayo;
Pel’ ayo nla
L’a nwo awon apa na.
4
Irapada t’a ti nreti,
O de pelu ogo nla;
Awon ti a gan pelu Re
Y’o pade Re loj’ orun!
ffAleluya,
Ojo Olugbala de.
5
Beni, Amin! k’a juba Re,
Lor’ ite Re ailopin,
Olugbala gba agbara;
Ogo at’ ijoba Re,
Jah, Jehofa,
Olorun aiku, ma bo!