Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 135

Kiyesi i, Emi mbo kankan, ere mi si mbe pelu mi.

Meter: 8.7.8.7.

Scripture: Ifi. 22:12

1

Jesu ti Baba ti gbega

Lat’ ipilese aye,

On kanna yio pada wa

Lati se ’dajo aye.

2

Wo! pipada bo Re daju,

A ki y’o ha mura de E?

K’a ba le ni ’gbala kikun

L’ojo ologo nla ni.

3

Y’O f’ara han l’awosanma,

Gbogbo oju ni y’o ri,

Ati awon t’o kan mo ’gi

Gbogb’ aye ni y’o jiyin.

4

Mo ’le fi ’gbagbo SQ wipe

Un o ba Jesu goke lo,

Si ’joba egberun odun,

Ati ti ayeraye.

5

Sugbpn awon miran ki y’o

Ba Oluwa wa goke,

Nitor’ ise won ko lere,

Ti won se l’oj’aye won.

6

A nreti dide Re sibe,

’WO ni ’reti gbogb’aye,

Ma bo, ’WO Olugbala wa,

Mu wahala wa d’opin.