Hymn 136
Ki enyin ki o mura sile; nitori ni wakati ti enyin ko ro tele li Omo-eniyan yio de.
Meter: 8.7.8.7.
Scripture: Mat. 24:44
1
mfAye ha nsaferi nipa
Bibo Krist’ nigba keji?
fBi orun on aye koja,
Oro na ki y’o ye lae.
2
fGege bi ojo Noa ti ri,
Beni wiwa Omo Eniyan;
’Torina e je ka mura,
Ki oko ’yawo to de.
3
Alabukun ni fun eni
Ti Kristi ba ti n sna;
On y’o si fi se olori,
N’nu ’joba ayeraye.
4
ffA! ayo ojo ajinde!
Ayo na y’o ti po to!
T’oko, aya, omo, ara,
Yoo maa korin ’rapada.
5
crJesu Oluwa ka wa ye
Si ’joba ologo yi;
Ka le dapo m’awon t’orun;
Lati ma yin O laelae.