Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 137

Ife gbogbo orile ede yio si de.

Meter: 8.7.8.7.D.

Scripture: Hag. 2:7

1

mfImole awon t’o joko

Leti ibebe iku,

Wa, jek’ itan san ife Re

Tu okunkun aye ka;

Eleda orun on aye,

La si okunkun eda,

Ki aimoye wa le kuro,'

Ki oju wa le riran.

2

mfA nreti dide Re sibe,

’Mole Re fun wa l’ayo

O le gbogbo eru wa lo,

O fi ’tunu f’okan wa;

Wa, f oju-’re Olorun han

Ti O fi ra wa pada;

Wa, Iwo Olugbala wa,

Mu ’hin-rere wa fun wa.

3

crFi iyonu nla Re gba wa,

Olprun alafia;

Jek’a mo adun igbala,

Dari ese wa ji wa,

Fi itoye irapada

Da okan ebi sile;

mfTo gbogbo okan ti nsako

Si ona alafia.