Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 138

Olorun nikan li okan mi duro je de; lati odo Re wa ni igbala mi.

Meter: 7.7.7.7.

Scripture: OD. 62:1

1

fWo Jesu t’a ti nreti

Lati gba wa low’ese.

’Gbawo ni ’gbala yo de,

Ti ao da ide ese?

2

mf’Wo Olugbala aye,

Wo ’banuje okan san,

crGbe eru wuwo kuro,

M’okan wa yo ninu ’se Re.

3

mfAwon woli eke po,

Won si nfi ’se ’yanu han,

Lati tan ayanfe je;

crOluwa da won lekun.

4

Oluwa awa mbe O,

Fun wa l’emi ’farada,

Lati le sin O d’opin,

Ka ma fara fun ’danwo.

5

mfMu okan t’o sun soji,

Le ailera wa jinna,

K’ale wa ni isokan

Titi ao fi ri O.

6

fOluwa Olubukun,

Lodo Re ni ayo wa,

Fun wa l’ore-ofe Re

K’oma ba wa gbe titi.