Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 14

Emi dubule, mo si sun’ mo si ji; Nitori ti Oluwa ti mi l’ehin.

Meter: C.M

Scripture: OD 3:5

1

mfNinu gbogbo ewu oru,

Oluwa l’o so mi;

Awa si tun ri ‘mole yi

A tun te ekun ba.

2

Oluwa, pa wa mo l’oni,

Fi apa Re so wa;

Kiki awon ti’wo pamo,

L’o nyo ninu ewu.

3

K’oro wa, ati iwa wa,

Wipe, tire l’awa;

Tobe t’imole otito

Le tan l’oju aye.

4

mpMa je k’a pada lodo Re,

Olugbala owon;

Titi ao f’oju wa ri

Oju Re li opin.