Hymn 140
O mbo, lati se idajo aye.
Meter: L.M.
Scripture: OD. 96:13
1
fOluwa mbo; aye yo mi,
Oke y’o sidi n’ipo won;
At’ irawo oju orun,
Y’o mu imole won kuro.
2
fOluwa mbo; bakanna ko
pBi o ti wa n’irele ri;
Odo-agutan ti a pa,
ppEni-iya ti o si ku.
3
fOluwa mbo; li eru nla,
L’owo ina pelu ija
L’or’ iye apa Kerubu,
Mbo, Onidajo araye
4
mfEyi ha li eniti nrin,
Bi ero l’opopo ayo?
Ti a se ’nunibini si?
ppA! Eni ti a pa l’eyi?
5
mfIka; b’e wo ’nu apata,
B’e wo ’nu iho, lasan ni;
fSugbpn igbagbo t’o segun,
ffY’o korin pe, Oluwa de.