Hymn 143
Kiyesi i, emi mbo kankan
Meter: C.M.
Scripture: Ifi. 22:7
1
fJesu kigbe pe, “Emi de,
T’emi ti ife nla”
Okan mi dahun pe, “Ma’bo”,
K’o mu igbala wa.
2
Wa, gba oran Baba Re ro;
Si mu ogo Re ran;
fWa, ji oku iranse Re
K’o si so won d’otun.
3
Ma bo wa ’larin ogun Re
Lati gb’oruko won;
K’o si m’ajo kikun pada
Lati y’ite Re ka.
4
Olurapada, wa kankan,
Mu ojo nla ni wa.
mfWa, k’okan wa ma ba daku,
Nitori pipe Re.