Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 144

Wakati mbo, ninu eyiti gbogbo awon ti o wa ni isa oku yio gbo ohun Re, Won si jade wa.

Meter: 8.7.8.7.4.7.

Scripture: Jn. 5:28-29

1

fOjo ’dajo, ojo eru!

Gbo bi ipe ti ndun to!

O ju egberun ara lo

O si nmi gbogbo aye.

pBi esun na

Y’o ti damu elese!

2

mfWo Onidajo l’awo wa,

T’o wo ogo nla l’aso.

Gbogbo won ti nwo ona Re.

’Gbana ni won o ma yo

pOlugbala,

Jewo mi ni ijo na.

3

fNi pipe Re o ku o ji

Lat’ okun, ile, s’iye:

Gbogbo ipa aye y’o mi,

Won o salo loju Re.

pAlaironu,

Yoo ha ti ri fun o?

4

mfEsu ti ntan o nisiyi,

Iwo ma se gbo tire,

’Gbati oro yi koja tan,

Y’o ri o ninu ina;

pIwo ronu

Ipo re ninu ina!

5

pLabe ippoju, at’egan,

K’eyi gba o n’iyanju;

Ojo Olorun mbo tete,

’Gbana ekun y’o d’ayo,

fA o segun

Gbati aye ba gbina.