Hymn 145
Gbogbo oju ni yio ri i.
Meter: S.M.
Scripture: Ifi. 1:7
1
Onidajo mbo wa,
Awon oku jinde,
Enikan ko le yo kuro
’Nu mole oju Re.
2
Enu ododo Re
Yio da ebi fun
Awon t’o so anu Re nu;
Ti won se buburu.
3
“Lo kuro l’odo mi
S’ina ’ti ko l’opin
Ti a ti pese fun
T’o ti n sote simi
4
Iwo ti duro to!
Ojo na o mbo wa,
L'aye at’orun o fo lo
Kuro ni wiwa Re.