Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 149

Sa wo o, mo mu ihinrere ayo nla fun yin wa.

Meter: 10.10.10.D.

Scripture: Lk.2:10

1

fJi, ’wo Kristian, k’o ki oro ayo

Ti a bi Olugbala araye;

Dide, k’o korin ife Qlorun

T’awon Angeli nko n’ijo kini;

Lat’ odo won n’ihin na ti bere;

Ihin Om’Olorun t’a bi s’aye.

2

mf’Gba na l’a ran akede angeli;

T’a so f awon olus’agutan pe,

“Mo mu ’hinrere Olugbala wa

T’a bi fun yin ati gbogbo aye,

Olorun mu l’eri Re se loni

A bi Olugbala, Krist’ Oluwa.

3

mfBi akede angel’ na ti so tan,

Opolopo ogun orun si de;

Won nkorin ayo t’eti ko gbo ri,

Orin Aleluya gba orun kan,

Ogo ni f’Olorun l’oke orun,

Alafia at’ife s’eniyan.

4

A ba le ma ranti nigbagbogbo

Pe, ’fe Olorun l’o gba ’raye la,

K’a to ’se Jesu t’o ra wa pada,

Lat’ ibuj’ eran de or’agbelebu;

K’a toro or’-ofe k’a le te le,

Titi ao tun r’oju Re Qlorun.

5

fNigbana ’gba ’ba de orun lohun

A o korin ayo t’irapada;

Ogo Eni t’a bi fun wa loni,

Y’o ma ran yi wa ka titi laelae;

A o ma korin ife Re titi,

Oba angeli, Oba eniyan.