Hymn 151
Nitori a bi Omo kan fun wa, a fi Omo kunrin kan fun wa.
Meter: 7777.7777.77.
Scripture: Isa. 9:6
1
Gbo eda orun nkorin:
“Ogo fun Oba t’a bi” .
p“Alafia l’aye yi”
crOlorun ba wa laja,
fGbogbo eda nde l’ayo,
E gberin, at’oke wa,
Kede pel’angeli pe
A bi Kristi ni Betlehem’.
CHORUS
Gbo Eda orun nkorin
Ogo fun Oba t’a bi.
2
Kristi t’a nyin l’ogo l’orun,
Kristi Oluwa titi lae,
Ni igbeyin, wo, o de,
Omo inu wundia!
W’Olorun di eniyan!
Olorun di eniyan
O dun mi k’o b’eeyan gbe
Jesu, Imanuel’ wa.
3
Wo, Alade alafia!
Wo o, orun ododo!
Omu ’mole iye wa,
’Lera mbe li apa re,
O bo ’go re s’apakan,
A bi k’eniyan ma ku;
A bi ko gb’eniyan ro,
A bi k’o le tun won bi.
4
Wa ’reti oril’ede,
F’okan wa se ’bugbe Re,
Nde, Iru Qmo ’birin,
Segun esu ninu wa,
Pa aworan Adam re,
F’aworan Re dipo re,
Adam’ ’keji lat’oke,
Gba wa pada s’ife re