Hymn 155
IWO Betlehemu, IWO ko kere julo nin ’awon Omo alade Juda.
Meter: 8.7.8.7.
Scripture: Mat. 2:6
1
fIlu t’o dara po l’aye
Betlehem’, ’wo ta won yo,
Ninu re l’Oluwa ti wa
Lati joba Israel’.
2
Ogo ti irawo ni ju
Ti orun owuro lo,
Irawo t’o kede Jesu
Ti a bi ninu ara,
3
Awon ’logbon ila-orun
Mu ’yebiye ore wa;
E wo bi won ti fi wura,
Turari, ojia fun.
4
Awon ebun iyebiye;
Turari, n f’okan s’oke,
Wura won nkede Oba won,
Ojia nfi ’boji Re han.
5
Jesu, ’Wo ti keferi nsin
Li ojo ifihan Re;
Fun O, Baba l’a f ogo fun
Ati fun Emi Mimo.