Hymn 157
Nitori a bi Olugbala fun yin loni ni ilu Dafidi, ti ise Kristi Oluwa.
Meter: C.M.
Scripture: Lk. 2:11
1
Bi awon Olus’agutan
Ti ns’agbo won l’oru;
Angel’ Oluwa sokale,
Ogo ran yin won ka.
2
Eru ba won pupo, sugbon
O ni - “E ma beru,
Ihin ayo ni mo mu wa
Fun yin at’araye,”
3
Fun yin n’iluDafid’, loni,
N’idile Dafidi,
A bi Olugbala ti se
Kristi, Oluwa wa;
4
Eyi ni y’o j’ami-Eyin
O ri om-Owo na,
A fi oja we, a si te
Si ibuje eran.
5
Bi angel’ na ti soro tan
Opo awon angel’
Fo de, won si nyin Olorun
Won nkorin ayo pe
6
Ogo ni f’Olorun loke
Alafia l’aye,
K’ife ’nurere s’eniyan
Bere, laini opin.