Hymn 160
A ti li aye alafia; ife inu rere si eniyan.
Meter: 8.7.8.7.
Scripture: Lk. 2:14
1
Alafia f’aye at’eeyan
L’orin t'awon angel’ ko;
Awon Olus’agutan gbo
T’ikede ibi Kristi.
2
Ni on oke Judea
N’imole ’rawo nla tan
Lati s’amona fun awon
Ti nwa ebun ’yanu yi.
3
Awon amoye meta ni
Ri imple nlanla na;
Won mu ebun wa f’Omo na,
Wura, turari, ojia.
4
Leba ibuje eran na
Won juba fun Oba won,
N’irele won f’ebun lele
F’eni to mu ’gbala wa.
5
Bi odun ti nyi lu odun
L’a tun nbi Krist’ ni titun
N’nu okan awon omo Re,
B’angeli ti so tele
6
A nri ’rawo na nisiyi
B’akoko ta bi Kristi;
Ki ’bukun Kristi je tire
B’odun ti nyi lu odun.