Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 161

Lati wasu ihinrere fun awon otosi, lati se awotan awon onirobinuje Okan, lati kede idasile fun awon igbekun.

Meter: C.M.

Scripture: Isa. 61:1

1

Gbo iro orin angeli

Ti ndun yi aye ka;

A bi Olugbala s’aye

Om’Olorun d’eniyan.

2

A bi Olugbala loto

Fun gbogbo agbaye;

Lati da wa n’de low’esu

Kuro ninu egbe.

3

Opo ogun orun si yo

Fun ’Mole to deyi,

Ogo f’Olorun lok’orun,

Alafia f’eniyan.

4

A ha mo b’o ti soro to

Lati f’ite sile,

Lati mu ago kikoro

Fun ’rapada en’yan!

5

E fi ope fun Olorun

Fun ife nlanla yi

To ran Omo Re kansoso

Wa s’aye osi yi.

6

’Wo Omo nat’a bi loni

F’alafia fun aye,

F’ore-ofe Re ba wa gbe

At’ayo ibi Re.