Hymn 164
Awao mayo, inu wayio si ma dun
Meter: 8.7.8.7.8.7.
Scripture: OD. 118:24
1
fOnigbagbo, ebu s’ayo,
Ojo nla l’eyi fun wa;
E gbo bi awon Angeli
Ti nf’ ogo fun Olorun:
Alafia, Alafia
Ni fun gbogbo eniyan.
2
ffKi gbogbo aye ho fayo,
K’a f’ogo fun Olorun,
Omo bibi Re l’o fun wa
mfT’a bi ninu Wundia:
En’ Iyanu, En’ Iyanu
Ni Omo t’a bi loni.
3
fNinu gbogbo rudurudu,
On ibi t’o kun aye,
Ninu idamu nla ese
L’Om’ Olorun wa gba wa:
Olugbimo, Olugbimo,
Alade Alafia.
4
fOlorun Olodumare
L’abi, bi omo titun;
Baba! Eni ayeraye
L’o di alakoso wa:
ffE bu s’ayo, E bu s’ayo,
Omo Dafidi joba.
5
pO wa gba wa L’OWO ese,
O wa d’onigbowo wa
Lati fo itegun Esu
A se ni Oba ogo:
fE ku ayo, E ku ayo,
A gba wa L’OWO iku.