Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 165

A wa si wa foribale fun

Meter: 8.7.8.7.8.7.

Scripture: Mat. 2:2

1

ffOnigbagbo, e bu s’ayo!

Ojo nla l’eyi fun wa;

K’orun fayo korin kikan,

K’ igbo at’odan gberin.

ffEho! Eyo! Eho! eyo!

Okun at’odo gbogbo!

2

fE jumo yo, gbogbo eda,

Laye ati lorun;

fKi gbogbo ohun alaye

Nile loke yin Jesu.

E f’ogo fun, E f’ogo fun,

Oba nla t’a bi loni!

3

ffGb’ohun yin ga, “Omo Afrik”

Eyin iran Yoruba;

Ke ‘Hosana!” l’ohun goro

Jake-jado ile wa.

K’oba gbogbo, K’oba gbogbo

Juba Jesu Oba wa.

4

fE damuso! E damuso!

ffE ho ye! k’e si ma yo.

Itegun esu fo wayi,

“Iru-omobirin” de!

Aleluya! Aleluya!

Olurapada, Oba.

5

E gb’ohun yin ga,

Serafu, Kerubu, leba ite;

Angeli at’ eyin mimo,

Pelu gbogbo ogun orun,

fEbawayo! Ebawayo!

Odun idasile de.

6

Metalokan, Eni Mimo,

Baba, Olodumare,

Emi Mimo, Olutunu,

Jesu, Olurapada,

Gba iyin wa, Gba iyin wa,

’Wo nikan l’ogo ye fun.