Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 166

Mo mu ihin ayo nla fun nyin wa.

Meter: L.M.

Scripture: Lk. 2:10

1

fOjo ayo nlanla na de,

Eyi t’ araye ti nreti;

crNigbat’ Olugbala w’aye

Nigbat’ a bi ninu ara.

2

fOlus’agutan ni papa

Bi won ti nso agutan won,

Ni ihin ayo na ko ba.

Ihin bibi Olugbala.

3

Angel’ iranse Oluwa

L’a ran si Won, alabukun,

Pelu ogo t’o tan julo,

Lati SO ihin ayo yi.

4

mpGidigidi l’eru ba won,

Fun ajeji iran nla yi;

f“Ma beru” l’oro iyanju

T’o t’enu Angeli na wa.

5

A bi Olugbala l’oni,

Kristi Oluwa aye ni;

N’ilu nla Dafidi l’o wa,

pN’ibuje eran l’atesi.

6

f“Ogo fun Olorun” l’orin

Ti eniyan y’o ko s’orun:

Fun ife Re laini opin,

T’o mu alafia w’aye.