Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 17

Ona mi iba je la sile lati ma pa olana Re Mo!

Meter: C.M

Scripture: OD119:5

1

mfOluwa, emi y’o korin

Anu at’idajo;

Nigbawo n’Iwo y’o fun mi

N’imole on iye

2

mo nfe lati t’ona pipe,

Ki nni okan pipe,

Ona, okan ati ile,

Nibiti Iwo mbe,

3

Mo nfe ki awon oloto

Je oluranwo mi;

Ki nfi won s’ore-imule

A t’omo-odo mi.

4

crKi yo si eke at-etan

Ninu ibugbe mi;

MpOluwa, Jek’Ibugbe mi

Ye fun O lati gbe!