Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 176

Oluwa, IWO li o ti nse ibujoko wa lati irandiron.

Meter: CM.

Scripture: OD. 90:1

1

fOlorun t’odun t’o koja

Iret’ eyi ti mbo;

Ib’isadi wa ni iji

At’ile wa laelae.

2

mpL’abe ojiji ite Re

L’awon eniyan Re ngbe,

fTito l’apa Re nikanso,

Abo wa si daju.

3

mfK’awon oke k’o to duro,

Tabi k’a to d’aye,

fLaelae IWO ni Olorun

Bakanna, l’ailopin!

4

Egberun odun l’oju Re

Bi ale kan l’o ri;

B’iso kan l’afemojumo

Ki orun k’o to la.

5

Ojo wa bi odo sisan,

Opo l’o si ngbe lo;

Won nlo, won di eni ’gbagbe

Bi ala ti a nro

6

fOlorun t’odun t’o koja,

Iret’ eyi ti mbo,

Ma s’abo wa ’gba ’yonu de

At’ ile wa laelae.