Hymn 178
IWO ma beru, nitori mo wa pelu re.
Meter: 11.11.11.11. & Ref.
Scripture: Isa. 41:10
1
mfN’ibere odun yi, odun titun yi
Oro itunu de, ti nle eru lo
pOhun keje jeje ti Baba Orun
crOdodo l’oro na, ti nm’okan wa yo
CHORUS
fE ma tesiwaju, Omo imole,
Oro Re ko le ye, O nduro titi.
2
f“Ma beru” l’oro na, “Mo wa pelu yin”
Emi n’iranwo yin at’agbara yin,
Emi y’o di yin mu, li owo ’tun mi,
Mo pe yin, mo yan yin, lati je temi.
3
fFun opo odun ti mbe niwaju wa,
Opo ni ipese t’o ti seleri:
Ipese f’alaini, f’awon elese.
F’awon t’a npon loju, fun alailera.
4
mfKo je fi wa sile, ko si ni ko wa,
Majemu Re daju ti ko le ye lae
ffA ro mo ’le riyi, eru ko bawa,
Olorun wa ti to, fun odun ti mbo.