Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 179

Olorun si wipe,..... Ki nwon ma wafun ami, akoko ojo ati fun Odun.

Meter: 8.7.8.7.4.7.

Scripture: Gen. 1:14

1

fOluwa alafia wa

L’O pase t’odun yipo;

Awa omo Re wa dupe

F’ odun tuntun t’ a bere

Yin Oluwa!

Oba nla t’O da wa si.

2

mfA dupe fun ipamo wa

Ni odun ti o koja;

A mbebe iranlowo Re

Fun gbogbo wa l’odun yi.

Je k’ Ijo wa

Ma dagba ninu Kristi.

3

fK’agba k’o mura lati sin

L’okan kan ni odun yi;

K’awon omode k’o mura

Lati s’aferi Jesu.

K’alafia

K’o se ade odun yi.

4

fK’Emi Mimo lat’oke wa

Be le wa ni odun yi;

Ki Alufa at’Oluko,

Pelu gbogbo Ijo wa

Mura giri

Lati josin f’Oluwa.