Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 18

Emi o ma korin anu Oluwa lailai.

Meter: 8.7.8.7

Scripture: OD 89:1

1

fL’ojojumo l’a ngbe O ga

Nigbati ile ba mo,

T’a ba kunle lati yin O

Fun anu ti owuro

2

L’ojojumo l’angbe O ga

Pel’orin n’ile-eko,

Lojojumo, pelu iyin,

L’a nse ise wa gbogbo.

3

L’ojojumo l’a ngbe O ga

Ninu orin k’a to sun

Awon Angel’gbo, won si nso

Awon aguntan Kristi

4

L’ojojumo l’a ngbe O ga

Ki se ni iyin lasan;

Otito ati igboran

Nf’ogo Re han ninu wa.

5

mfL’ojojumo l’a ngbe O ga

Gba t’a ngbiyanju fun krist’

Lati ma farada iya

K’a pa ese run n’nu wa.

6

fL’ojojumo l’a ngbe O ga

Tit’ ojo wa y’o fi pin

Tao simi n’nu lala gbogbo

L’alafia d’ojo Re