Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 186

Olorun si wipe, ki imole ki o wa L’ofurufu fun ami, fun akoko, fun ojo, ati fun odun.

Meter: C.M.

Scripture: Gen. 1:14

1

mfOlorun wa, je k’iyin Re

Gb’ohun gbogbo wa kan;

Owo Re yi ojo wa po,

Odun miran si de.

2

Ebo wa ngoke sodo Re,

Baba, Olore wa:

Fun anu ododun ti nsan

Lati odo Re wa.

3

N’nu gbogbo ayida aye,

K’anu Re wa sibe:

B’ore Re si wa si ti po,

Beni k’iyin wa po.

4

N’nu gbogbo ayida aye,

A nri aniyan Re;

JOWO, je k’anu Re ’kanna

Bukun odun titun.

5

B’ayo ba si wa, k’ayo na'

Fa wa si odo Re;

B’iya ni, awa o korin

B’ibukun Re pelu.