Hymn 19
Nigbati iwo ba sun, yio ma so O.
Meter: L.M
Scripture: Owe 6:22
1
fOgo f’Olorun l’ale yi
Fun gbogbo ore Imole,
So mi, Oba awon Oba
L’abe ojiji iye Re.
2
mpOluwa f’ese mi ji mi,
Nitori omo Re, loni
K’emi le wa l’alafia,
Pelu iwo ati aye
3
mfJe k’okan mi le sun le O,
K’orun didun p’oju mi de,
Orun ti y’o m’ara mi le,
Ki nle sin O li owuro
4
mpBi mo ba dubule laisun,
F’ero orun kun okan mi,
Ma je ki nl’ala bururu,
Ma je k’ipa okun bo mi
5
ffYin Olorun, Ibu ore;
E yin, eyin eda aye,
E yin, eyin eda Orun,
Yin Baba, Omo on Emi