Hymn 210
Nitori Olorun fe araye tobe ge, ti o fi Ome bibi Re kan soso fun ni
Meter: 7.7.8.7.6.7.8.7. & Ref.
Scripture: Jn. 3:16
mfAgogoihinrere
Nlu lat’ilu de ilu,
’Bukun ati ’gbala ofe
Ni won fun o at’emi,
mpOlorun f’ araye
T’o fi Omo Re fun wa;
fF’enikeni ti o gb’A gbo
Y’o ni ’ye ainipekun.
f’Hinrere b’o ti ndun
Lati ilu de ilu,
’Hinrere l’ofe ni,
’Hinrere to n’ibukun.
mfAgogo ihinrere
Npe wa si ase nla na,
fJo, ma ko ipe Oluwa,
Ma si ko ’pe or’ofe,
mpAkara ’ye l’Emi,
Je n’nu re okan ebi,
pB’ese re pon bi ododo
mf’Won y’o funfun bi owu.
Agogo na nma nkilo
B’o ti nlu lojojumo
Ni p’ohun to le de b’awon
To f akoko jafara
fS’asala f’emi re,
Ma duro ni petele
mfMase b’oju wo eyin re,
Ki egbe ma se ba o.
fAyo ni agogo na,
ffFi nlu kakiri aye,
NSO nipa ti idariji
Ti Jesu y’o fi fun wa
’Hinrere t’ayo nla
L’o mu wa fun gbogb’ eniyan,
fFun ol’abi Olugbala
Krist’ Oluwa at’Oba.