Hymn 220
Eje Jesu Kristi Omo re ni n we wanu kuro ninu ese wa gbogbo.
Meter: CM.
Scripture: I Jn. 1:7
1
mfNihinyi n’isimi gbe wa,
Niha re t’ eje nsan;
Eyi nikan n’ireti mi,
pPe Jesu ku fun mi.
2
Olugbala, Olorun mi,
Orisun f’ese mi;
Ma f’eje Re won mi titi,
K’ emi le di mimo.
3
mpWe mi, si se mi ni Tire,
We mi, si je temi;
We mi, k’ is’ ese mi nikan,
Owo at’ okan mi.
4
fMa sise l’okan mi, Jesu,
Titi ’gbagbo y’o pin;
Tit’ ireti y’o fi dopin,
T’ okan mi y’o simi.