Hymn 228
Nitori Omo mi yi ti ku, o si tun ye; O ti nu, a si ri i.
Meter: 9.8.9.7.& Rel .
Scripture: Lk. 15:24
1
Lekan, mo j’elese, sugbon mo
Ti gba ’dariji l’od’Oluwa,
L’ofe l’a fifun mi, mo si ri
Pe O npa oro Re mo.
CHORUS
Oko titun t’a ko sile n’n’ogo
T’emi ni toto, t’emi
Awon angeli mimo nko ’rin na
Elese kan wa le
Tor’oko titun kan ti a ko n’n’ ogo
T’emi ni, toto temi,
Leyin ’dariji ese, orun ni mo nlo
Nko tun sako mo.
2
Mo fi ’rele kunle l’ese Krist’
Mo si mberu ’binu Olorun,
Nigbat’ a si orun, ti mo ri
P’a ko ’ruko mi sile;
3
Or’-ofe nikan l’o gba mi la,
Ayo ki l’o de si okan mi
A ti dariji mi mo si mo
P’eJe Krist’ mu mi pe.