Hymn 24
Nigbati o di asale, nwon kogbogbo Awon Alaisan to o wa.
Meter: L.M
Scripture: MK 1:32
1
mfL’oju ale ‘gba’t orun wo,
Won gbe abirun w’odo Re,
POniruru ni asisan won,
FSugbon won f’ayo lo’ le won
2
mfJesu l’ oj’ale yi,
A sun m’O t’awa t’arun wa,
CrBi a ko tile le ‘ri O,
Sugbon, a mo p’O sunmo wa.
3
mpOlugbala, wo osi wa,
Opo nsaisan, opo nk’edun,
Opo ko ni ‘fe si O to.
Opo n’ife won si tutu.
4
Opo ti ri p’asan l’aye
Sibe nwon ko f’aye sile,
Opo l’ore b n’inu je,
Sibe won ko fi O s’ore
5
Ko s’okan ninu wa t’o pe
Gbogbo wa si ni elese,
Awon t’o si nsin O toto
Mo ara won ni alaipe
6
mfSugbon Jesu, Olugbala,
Eni bi awa ni ‘Wo se
‘Wo ti ri’danwo bi awa
‘Wo si ti mo ailera wa.
7
Agbar’owo Ro wa sibe,
Ore Re si ni agbara,
PGbo adura ale wa yi,
CrNi anu, wo gbogbo wa san.