Hymn 243
Lati wasu idasile fun awon igbekun.
Scripture: Lk. 4:18
mfLati ’nu ide ibanuje
Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa gba ominira at’ayo,
Jesu mo wa ’do Re.
Alai san, emi nfe iwosan;
Alaini, SO mi di Oloro;
crElese. mo wa si odo Re;
Jesu, mo wa ’do Re.
Ninu ’tiju ati ofo mi Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa jere nla n’nu iku Re,
Jesu mo wa ’do Re,
’WO ni itunu fun ’banuje;
’WO n’isimi fun gbogbo iji,
Orin dipo idanwo gbogbo,
Jesu mo wa ’do Re.
crNinu rudurudu aye yi,
Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s’abe ase anu Re,
Jesu mo wa’do Re,
Mu mi kuro n’nu ife ara,
Kuro ninu aye asan yi,
Ki nle wa fi iye fo g’oke,
Jesu mo wa ’do Re.
crN’nu eru iku at’iboji
Jesu mo de, Jesu mo de,
Mo wa s’inu ayo ile mi,
Jesu mo wa ’do Re,
Lati ’nu iho iparun nla
Sinju alafia t’ o jinle
Lati wa w’ oju Re; ologo,
Jesu mo wa’do Re.