Hymn 248
Nitori ife Kristi nro wa.
Meter: S.M
Scripture: IIKor. 5:14
1
A! nibo ni mba lo,
Pelu ese nla mi
Tani mba f’ iponju mi han
Ti mba ro ’jo mi fun?
2
Olugbala npe mi;
Ese ti mo duro?
O npe elese t’are mu,
Sibe mo fa seyin
3
Ki l’o fa mi seyin
Ti nko le fi sile
Ti ki o jek’ Olugbala
Gba gbogbo okan mi.
4
Ohun egun aimo
T’o sa lumo ninu
Orisa ti nko fe jewo
Ese ’koko n’nu mi.
5
Jesu, fi’dena na
Ti nko fe ri, han mi;
Jeki nle wadi ohun na
Ti nle mi l’odo Re.
6
Oluwa di okan
F’ ipa Re han n’nu mi;
Tan ’mole si okunkun mi,
'K’o si ’boju kuro.
7
Mo gbagbe wayi pe .
Anu mbe ninu Re;
Oluwa, jek’ o ri fun mi
Gege b’igbagbo mi!
8
Iwo nfe mu’dena
Ti njbe n’nu mi kuro;
Mu kuro, un o si jewo pe
Kiki ’fe l’Olorun