Hymn 251
Tali Olorun bi IWO ti o ndari Aise dede ji.
Meter: 8.8.8.D.
Scripture: Mika 7:18
1
mfOlorun ‘yanu ogo Re,
Nhan ninu gbogbo ise Re,
Sugbon or’ofe ’dariji,
Je ohun iyanu julo
Olorun tani dabi Re,
Ore tani po bi Tire?
2
mpN’iyanu at’ayo l’a gba
Idariji Olorun wa,
’Dariji f’ese to tobi
T’eje Jesu s’etutu fun,
Olorun tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?
3
cr’Dariji lat’ow’ Olorun
’Dariji fese to tobi
’Dariji ni p’eje Jesu
’Dariji m’olote wa ’le
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?
4
pJo, je k’ore-ofe Re yi
Ife iyanu nla Re yi
crFi iyin kun gbogbo aye,
Bi t’egbe akorin l’oke
Olorun, tani dabi Re?
Ore tani po bi Tire?