Hymn 252
Ibukun ni fun awon ti a dari Aisedede Won ji, ti a si bo ese won mole.
Meter: L.M & Ref
Scripture: OD. 32:1
1
mfE ro didun nit’ese mi.
T’a sin s’abe omi okun
’Gbati agbara Olorun
Dide fun ’gbala okan mi.
CHORUS
f“Iwo yooo ran ese won lo s’ogbo okun”
Ileri Oluwa ni, o si to fun mi
B’omi okun tile nho pelu bibi re
Y’o rele, y’o si gbe, ko le de odo mi
Nitori Olorun nikan l’o kawo igbi-
Omi nla ti ’nu okun.
2
mfWon ki y’o tun gb’ogun ti mi,
Tabi yo okan mi lenu,
cr’Tori agbara Olorun
Ni y’o mu idariji wa.
3
mfKo si wahala to le mu
Ese mi wa si iranti,
fOkan mi s’owon l’oju Re,
Y’o d’abobo nigbagbogbo.