Hymn 258
Jesu Oluf'okan mi
Meter: 7.7.7.7.D.
Scripture: OD. 143:9
1
mpJesu Oluf’okan mi,
Je ki nsala s’aya Re,
crSa t’irumi sunmo mi.
Sa ti iji nfe soke;
mfPa mi mo, Olugbala
Tit’ iji aye y’o pin,
diTo mi lo s’ebute Re,
pNikeyin, gba Okan mi.
2
mfAbo mi, emi ko ni,
IWO l’okan mi ro mo;
diMa femi nikan sile;
Gba, mi si tu mi ninu,
crIwo ni mo gbekele;
IWO n’iranlowo mi;
mfMa sai fiye apa Re
Dabo b’ori aibo mi.
3
mfKrist’ ’Wo nikan ni mo fe;
N’nu Re mo r’ohun gbogbo
Gb’eni to subu dide,
W’alaisan, to afoju,
Ododo l’oruko Re,
pAlais’ododo l’emi
Mo kun fun ese pupo,
mfIwo kun fun ododo.
4
cr’WO l’opo ore-ofe,
Lati fi bo ese mi;
Je ki omi iwosan
We inu Okan mi mo;
fIWO l’orisun iye,
Je ki mbu n’nu Re l’ofe,
Ru jade n’nu okan mi,
Si iye ainipekun.