Hymn 259
E mayo ninu Oluwa nigba gbogbo, mo si tun wi, “E mayo.”
Meter: 9.8.9.8. & Ref.
Scripture: Fili. 4:4
1
O mi nyo ninu Oluwa
’Tori O je iye fun mi
Ohun Re dun pupo lati gbo
Adun ni lati r’oju Re.
CHORUS
Emi nyo-ninu Re
Emi nyo ninu Re
Gba gbogbo lo fayo kun okan mi
’Tori emi nyo n’nu Re.
2
O ti pe t’O ti nwa mi kiri,
’Gbati mo rin jina s’agbo,
O gbe mi wa sile l’apa Re
Nibiti papa tutu wa.
3
Ire at’anu Re yi mi ka,
Or’-ofe Re nsan bi odo,
Emi Re nto, o si nse ’tunu,
O mba mi LO si ’bikibi.
4
Emi y’o dabi Re ni ’jo kan,
Uno s’eru wu womi kale,
Titi di ’gbana uno s’oloto,
Ni sise oso f’ade Re.