Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 267

A won oke nla ati awon oke Kekeke yio bu si orin niwaju yin.

Meter: 7.6.7.6.7.6.D.

Scripture: Isa. 55:12

1

fGbogb’ aye kun fun orin,

Mo ngbo nibi gbogbo;

Awon ’tanna papa ndun

Layo n’nu afefe.

Loke, li ayika mi,

Orin jeje nyin lo

Oba ogo wa mi ri,

Orin wa n’n’ okan mi!

CHORUS

mfEje Jesu Kristi nsan,

Igbi Re yi mi ka;

Ife mole lokan mi,

Orin wa n’n’okan mi!

2

crTeleri, imi edun

Li okan mi ma nfe;

Nitori ailera mi

Ni o se fi ri be

Nigba mo fokan mi fun

Oro Re wo mi san,

Lae mo wa lodo Kristi

Orin wa ri’n’okan mi!

3

mpGbogb’ aye mi ti kun fun,

’Banuje at’aro;

Sugbon lat’isiyi lo

Ororo ayo de;

Adura d’orin iyin

Mo si wa nlepa nso

Ni adura at’ise

Orin wa n’n’okan mi!

4

fBeni okan mi si nyo

Si oro Oluwa;

Gbogbo ’gba lo si nkorin

Gege b’awon eye;

Emi ko mo ibiti

Orin harp na ti ndun,

mpMo mo p’orun sunmo mi.

fOrin wan’n’ okan mi.