Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 270

Nigbati okan ninu WON ripe a mu on larada o pada, o si yin Olorun l’ogo.

Meter: 10.10.10.10 & Ref.

Scripture: Lk. 17:15

1

mfEtutu eje Krist’ t’a ta sile,

mpLori ’gi Kalfari l’o gba mi la,

Sugbon mo nfe isun to ju yi lo

Ekun ibukun Re l’okan mi nfe lati mo.

CHORUS

fMo ngbe l’aye bi l’orun,

Mo f’aye mi fun Jesu,

Mo l’ayo ninu ominira ti O fun mi;

Oro na ti On ti SO

Tija gbogbo ide mi;

’Seju kokan aye mi si je ’bukun orun.

2

fT’emi l’ayo lat’orisun ife

Ebun Orun yi lo wu mi julo.

Mo si wa ni alafia pipe

Nigbati emi Re fun mi l’oro ominira.

3

mfIwo fe mo ekun ore Baba?

IWO fe gbe n’nu ibu oro Re?

fGbagbo; ileri Re otito ni;

Si gba ominira t’o ni ’bukun t’O fi fun O