Hymnize

CAC Hymn Collection

Hymn 273

Enikeni ti o ba to mi wa, Emi ki yio taa nu bi o ti wu ki o ri.

Meter: 12.11.12.12. & Ref.

Scripture: Jn. 6:37

1

mf’Gba mo t’Oba mi wa pelu okan tite,

Ti mo mbebe for’ofe n’iwaju ’te Re,

fAyo ti mo ri l’oju Re bo ti dun to!

B’ayaba Esther, O n’opa anu si mi.

CHORUS

ffOpa ife loje ati t’idariji,

L’ofe si ni opa anu na,

Oba orun b’oju wo ’le lat’oke

O si na opa na si mi.

2

mpMo ti sako jina to ninu ese mi;

Ninu ope mo ti padanu pupo,

crMo so ’reti nu ’gbat’ o ku emi nikan,

Mo gb’ohun adun Re, sunmo ’te mimo

3

crBi ’wo ba je le f okan re fun Krist’ Oba

Y’o fi se ’le, ko si ni kuro nibe,

fSa ronupiwada, ayo y’o je tire,

Nitori Jesu y’O n’opa anu si O