Hymn 288
Hosanna fun Omo Dafidi
Meter: 7.6.7.6.D.
Scripture: Mat. 21:9
1
mf’Wo l’Oba Israeli,
Om’alade Dafid’
T’O wa l’oko Oluwa;
Oba Olubukun,
CHORUS
ffGbogb’ogo, iyin, ola
Fun O Oludande,
S’Eni t’awon omode
Nko Hosanna didun!
2
ffEgbe awon Maleka
Nyin O l’oke giga;
Awa at’eda gbogbo
Si dapo gbe ”rin na.
3
fAwon Hebru lo s’aju
Pelu imo 0pe;
Iyin, adua at - orin
L’a mu wa ‘waju Re
4
mfSi O s’aju iya Re,
Won korin iyin won!
’Wo t’agbega nisiyi
L’an korin iyin si.
5
cr’WO gba orin iyin won,
Gb’adura t’a mu wa,
’WO ti nyo s’ohun rere,
Oba wa Olore,